ORIKI OWU*** *** omo olowu oduru omo a fegbe sere owu kii ranro, sugbon awii menu kuro no towu popondo l'ara owu nje aje f'ajaga b...
ORIKI OWU*** *** omo olowu oduru
omo a fegbe sere
owu kii ranro, sugbon
awii menu kuro no towu
popondo l'ara owu nje
aje f'ajaga bo'run
Awa lomo olowu iji
Omo olowu Oduru,awa lomo asunkungbade
aforogboye atewo lafi
gboye lowu tiwa
awa lomo amolese bi alari
alari molese ti nwole omo oba nile aro
Bi ase to lansoge to,bi baba wa se lowo to
lansoge to
omo owu ki ran oro awimenu kuro ntowu
awa lomo woyira ka ma ba ra erukeru nitori
erukeru ama bi lala
lenu
Owu l’a ko da o
Bi e d’owu
E beere wo
Owu l’ako da o
Bi e de’fe
E bere wo o
Owu l’a ko da o
Bi e de’le
E kaa ‘tan wo
Owu l’a ko da o
Bi e de’le
E ka ‘tan wo o